Hosea 14
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
Ìwòsàn ń bẹ fún àwọn tó ronúpìwàdà
14 Yípadà ìwọ Israẹli sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.
Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ!
2 (A)Ẹ gba ọ̀rọ̀ Olúwa gbọ́,
kí ẹ sì yípadà sí Olúwa.
Ẹ sọ fún un pé:
“Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá
kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá,
kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ
3 Asiria kò le gbà wá là;
A kò ní í gorí ẹṣin ogun
A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé
‘Àwọn ni òrìṣà wa
sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe;
nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn
aláìní baba tí ń rí àánú.’
4 “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn,
Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́,
nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn.
5 Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli
wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì
Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò
6 Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà,
Dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi
Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni.
7 Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀.
Yóò rúwé bi ọkà.
Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà,
òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni.
8 Ìwọ Efraimu; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà?
Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ.
Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù,
èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.”
9 (B)Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí
Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn.
Títọ́ ni ọ̀nà Olúwa
àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn
Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.