Marku 3:12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
12 (A)Ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn gidigidi, kí wọn má ṣe fi òun hàn.
Read full chapter
Marku 5:43
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
43 (A)Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.
Read full chapter
Marku 7:36
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
36 (A)Jesu pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó.
Read full chapter
Marku 8:30
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
30 (A)Ṣùgbọ́n Jesu kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni.
Read full chapter
Marku 9:9
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
9 (A)(B) Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má ṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jíǹde kúrò nínú òkú.
Read full chapter
Lefitiku 14:2
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
2 (A)“Èyí ni àwọn ìlànà fún ẹni tí ààrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú ní àkókò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, bí a bá mú un tọ àlùfáà wá.
Read full chapterCopyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.